Luke 6:6-11

6 aNí ọjọ́ ìsinmi mìíràn, ó wọ inú Sinagọgu lọ, ó sì ń kọ́ni, ọkùnrin kan sì ń bẹ níbẹ̀ tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ rọ. 7Àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisi ń ṣọ́ ọ, bóyá yóò mú un láradá ní ọjọ́ ìsinmi; kí wọn lè rí ọ̀nà láti fi ẹ̀sùn kàn án. 8Ṣùgbọ́n ó mọ èrò inú wọn, ó sì wí fún ọkùnrin náà tí ọwọ́ rẹ̀ rọ pé, “Dìde, kí o sì dúró láàrín.” Ó sì dìde dúró.

9Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Èmi bi yín léèrè, Ó ha tọ́ láti máa ṣe rere ni ọjọ́ ìsinmi, tàbí láti máa ṣe búburú? Láti gba ọkàn là, tàbí láti pa á run?”

10Nígbà tí ó sì wo gbogbo wọn yíká, ó wí fún ọkùnrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ.” Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀: ọwọ́ rẹ̀ sì padà bọ̀ sípò gẹ́gẹ́ bí èkejì. 11Wọ́n sì kún fún ìbínú gbígbóná; wọ́n sì bá ara wọn rò ohun tí àwọn ìbá ṣe sí Jesu.

Copyright information for YorBMYO